< Psalms 63 >

1 Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda. Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ, òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi, ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi. 2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ. 3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ. 4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ. 5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́. 6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru. 7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ. 8 Ọkàn mí fà sí ọ: ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró. 9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun; wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé. 10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀. 11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.

< Psalms 63 >