< Psalms 63 >
1 Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda. Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ, òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi, ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi.
A psalm of David, when he was in the wilderness of Judah. O God, my God, you, you do I seek: my heart thirsts for you, my body faints for you in a parched and waterless land.
2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ.
As I in the temple have seen you, beholding your power and your glory,
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ.
for better than life is your kindness: my lips shall utter your praise.
4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
So, while I live, I will bless you, and lift up my hands in your name.
5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
As with marrow and fat am I feasted; with joyful lips I will praise you.
6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
I call you to mind on my bed, and muse on you in the night watches;
7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
for you have been my help, I joyfully sing in the shadow of your wings.
8 Ọkàn mí fà sí ọ: ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
I cling close after you, your right hand holds me up.
9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun; wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
But those who seek after my life shall go down to the depths of the earth,
10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.
given o’er to the power of the sword, or as prey for jackals to devour.
11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.
But the king shall rejoice in God: all who own his allegiance will glory. For the mouth of the false shall be stopped.