< Psalms 62 >

1 Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá.
למנצח על ידותון מזמור לדוד אך אל אלהים דומיה נפשי ממנו ישועתי׃
2 Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.
אך הוא צורי וישועתי משגבי לא אמוט רבה׃
3 Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ?
עד אנה תהותתו על איש תרצחו כלכם כקיר נטוי גדר הדחויה׃
4 Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. (Sela)
אך משאתו יעצו להדיח ירצו כזב בפיו יברכו ובקרבם יקללו סלה׃
5 Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.
אך לאלהים דומי נפשי כי ממנו תקותי׃
6 Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
אך הוא צורי וישועתי משגבי לא אמוט׃
7 Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi.
על אלהים ישעי וכבודי צור עזי מחסי באלהים׃
8 Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.
בטחו בו בכל עת עם שפכו לפניו לבבכם אלהים מחסה לנו סלה׃
9 Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n, lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí.
אך הבל בני אדם כזב בני איש במאזנים לעלות המה מהבל יחד׃
10 Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.
אל תבטחו בעשק ובגזל אל תהבלו חיל כי ינוב אל תשיתו לב׃
11 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, “Ti Ọlọ́run ni agbára,
אחת דבר אלהים שתים זו שמעתי כי עז לאלהים׃
12 pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú; nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.”
ולך אדני חסד כי אתה תשלם לאיש כמעשהו׃

< Psalms 62 >