< Psalms 61 >

1 Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi. Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; tẹ́tí sí àdúrà mi.
For the leader. On stringed instruments. Of David. Hear my cry, O God, be attentive to my prayer.
2 Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
From the ends of the earth I call unto you, when my heart is faint: lead me to the rock that is high above me.
3 Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
For you are a refuge to me, a strong tower in face of the foe.
4 Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
O to be guest in your tent forever, hiding beneath your sheltering wings! (Selah)
5 Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run; Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
For you, O God, do hear my vows, and grant the desires of those who fear you.
6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn, ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Add many days to the life of the king; may his years endure throughout all generations.
7 Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.
In the presence of God be he throned forever; may kindness and faithfulness watch over him.
8 Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.
And I will sing praise to your name forever, paying my vows day after day.

< Psalms 61 >