< Psalms 6 >
1 Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ.
For the Chief Musician; on stringed instruments, upon the eight-stringed lyre. A Psalm by David. LORD, don’t rebuke me in your anger, neither discipline me in your wrath.
2 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
Have mercy on me, LORD, for I am faint. LORD, heal me, for my bones are troubled.
3 Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?
My soul is also in great anguish. But you, LORD—how long?
4 Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
Return, LORD. Deliver my soul, and save me for your loving kindness’ sake.
5 Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú? (Sheol )
For in death there is no memory of you. In Sheol, who shall give you thanks? (Sheol )
6 Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
I am weary with my groaning. Every night I flood my bed. I drench my couch with my tears.
7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
My eye wastes away because of grief. It grows old because of all my adversaries.
8 Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
Depart from me, all you workers of iniquity, for the LORD has heard the voice of my weeping.
9 Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi.
The LORD has heard my supplication. The LORD accepts my prayer.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.
May all my enemies be ashamed and dismayed. They shall turn back, they shall be disgraced suddenly.