< Psalms 56 >
1 Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi; ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà sí mi, wọn ń ni mi lára.
For the choirmaster. To the tune of “A Dove on Distant Oaks.” A Miktam of David, when the Philistines seized him in Gath. Be merciful to me, O God, for men are hounding me; all day they press their attack.
2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́, àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.
My enemies pursue me all day long, for many proudly assail me.
3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí, èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
When I am afraid, I put my trust in You.
4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ, nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?
In God, whose word I praise— in God I trust. I will not be afraid. What can man do to me?
5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́, wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
All day long they twist my words; all their thoughts are on my demise.
6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba. Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
They conspire, they lurk, they watch my steps while they wait to take my life.
7 San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn; ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.
In spite of such sin, will they escape? In Your anger, O God, cast down the nations.
8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omijé mi sí ìgò rẹ, wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
You have taken account of my wanderings. Put my tears in Your bottle— are they not in Your book?
9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́ nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.
Then my enemies will retreat on the day I cry for help. By this I will know that God is on my side.
10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
In God, whose word I praise, in the LORD, whose word I praise,
11 nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi: ẹ̀rù kì yóò bà mí. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
in God I trust; I will not be afraid. What can man do to me?
12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run: èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
Your vows are upon me, O God; I will render thank offerings to You.
13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú, kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.
For You have delivered my soul from death, and my feet from stumbling, that I may walk before God in the light of life.