< Psalms 55 >

1 Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi. Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run, má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
למנצח בנגינת משכיל לדוד האזינה אלהים תפלתי ואל תתעלם מתחנתי׃
2 gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn. Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
הקשיבה לי וענני אריד בשיחי ואהימה׃
3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni, nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú; nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi, wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.
מקול אויב מפני עקת רשע כי ימיטו עלי און ובאף ישטמוני׃
4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú; ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
לבי יחיל בקרבי ואימות מות נפלו עלי׃
5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi; ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
יראה ורעד יבא בי ותכסני פלצות׃
6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
ואמר מי יתן לי אבר כיונה אעופה ואשכנה׃
7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré, kí ń sì dúró sí aginjù;
הנה ארחיק נדד אלין במדבר סלה׃
8 èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò, jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”
אחישה מפלט לי מרוח סעה מסער׃
9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú, nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
בלע אדני פלג לשונם כי ראיתי חמס וריב בעיר׃
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri; ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
יומם ולילה יסובבה על חומתיה ואון ועמל בקרבה׃
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀; ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.
הוות בקרבה ולא ימיש מרחבה תך ומרמה׃
12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi, èmi yóò fi ara mọ́ ọn; tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi, èmi ìbá sá pamọ́ fún un.
כי לא אויב יחרפני ואשא לא משנאי עלי הגדיל ואסתר ממנו׃
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
ואתה אנוש כערכי אלופי ומידעי׃
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀, bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.
אשר יחדו נמתיק סוד בבית אלהים נהלך ברגש׃
15 Kí ikú kí ó dé bá wọn, kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú, jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà, nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn. (Sheol h7585)
ישימות עלימו ירדו שאול חיים כי רעות במגורם בקרבם׃ (Sheol h7585)
16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; Olúwa yóò sì gbà mí.
אני אל אלהים אקרא ויהוה יושיעני׃
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú, o sì gbọ́ ohùn mi.
ערב ובקר וצהרים אשיחה ואהמה וישמע קולי׃
18 Ó rà mí padà láìléwu kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
פדה בשלום נפשי מקרב לי כי ברבים היו עמדי׃
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì (Sela) nítorí tí wọn kò ní àyípadà, tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.
ישמע אל ויענם וישב קדם סלה אשר אין חליפות למו ולא יראו אלהים׃
20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀; ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
שלח ידיו בשלמיו חלל בריתו׃
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́, ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.
חלקו מחמאת פיו וקרב לבו רכו דבריו משמן והמה פתחות׃
22 Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa yóò sì mú ọ dúró; òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
השלך על יהוה יהבך והוא יכלכלך לא יתן לעולם מוט לצדיק׃
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi wá sí ihò ìparun; àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn, kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn. Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.
ואתה אלהים תורדם לבאר שחת אנשי דמים ומרמה לא יחצו ימיהם ואני אבטח בך׃

< Psalms 55 >