< Psalms 50 >
1 Saamu ti Asafu. Olúwa, Ọlọ́run alágbára, sọ̀rọ̀ kí o sì pe ayé jọ láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀.
[A Psalm by Asaph.] The Mighty One, God, Jehovah, speaks, and summons the earth from the rising of the sun to its setting.
2 Láti Sioni wá, pípé ni ẹwà, Ọlọ́run tí ń tan ìmọ́lẹ̀
Out of Zion, the perfection of beauty, God shines forth.
3 Ọlọ́run ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́, iná yóò máa jó níwájú rẹ̀, àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká.
Our God comes, and does not keep silent. A fire devours before him. It is very stormy around him.
4 Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé, kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀.
He calls to the heavens above, to the earth, that he may judge his people:
5 “Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
"Gather my faithful ones together to me, those who have made a covenant with me by sacrifice."
6 Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀, nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni onídàájọ́.
The heavens shall declare his righteousness, for God himself is judge. (Selah)
7 “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ: èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
"Hear, my people, and I will speak; Israel, and I will testify against you. I am God, your God.
8 Èmi kí yóò bá ọ wí nítorí àwọn ìrúbọ rẹ, tàbí ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, èyí tí ó wà níwájú mi ní ìgbà gbogbo.
I do not rebuke you for your sacrifices. Your burnt offerings are continually before me.
9 Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí o kọ́ fún un, tàbí kí o mú òbúkọ láti inú agbo ẹran rẹ̀
I have no need for a bull from your stall, nor male goats from your pens.
10 nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmi àti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
For every animal of the forest is mine, and the livestock on a thousand hills.
11 Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńlá àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà ní orí ilẹ̀ ni tèmi.
I know all the birds of the mountains. The wild animals of the field are mine.
12 Bí ebi tilẹ̀ ń pa mí, èmi kì yóò sọ fún ọ, nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbo tí ó wa ní inú rẹ̀.
If I were hungry, I would not tell you, for the world is mine, and all that is in it.
13 Ǹjẹ́ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbí mú ẹ̀jẹ̀ òbúkọ?
Will I eat the flesh of bulls, or drink the blood of goats?
14 “Rú ẹbọ ọpẹ́ sí Ọlọ́run, kí o sì san ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ọ̀gá-ògo.
Offer to God the sacrifice of thanksgiving. Pay your vows to the Most High.
15 Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”
Call on me in the day of trouble. I will deliver you, and you will honor me."
16 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú: “Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ, tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
But to the wicked God says, "What right do you have to declare my statutes, that you have taken my covenant on your lips,
17 Ìwọ kórìíra àṣẹ mi, ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
seeing you hate instruction, and throw my words behind you?
18 Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn, ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
When you saw a thief, you consented with him, and have participated with adulterers.
19 Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú, ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
"You give your mouth to evil. Your tongue frames deceit.
20 Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ, ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
You sit and speak against your brother. You slander your own mother's son.
21 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́; ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí, èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.
You have done these things, and I kept silent. You thought that I was just like you. I will rebuke you, and accuse you in front of your eyes.
22 “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
"Now consider this, you who forget God, lest I tear you into pieces, and there be none to deliver.
23 Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe, kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”
Whoever offers the sacrifice of thanksgiving glorifies me; and to him who orders his conduct I will show the salvation of God."