< Psalms 5 >

1 Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi. Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa, kíyèsi àròyé mi.
For the choirmaster, to be accompanied by flutes. A Psalm of David. Give ear to my words, O LORD; consider my groaning.
2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
Attend to the sound of my cry, my King and my God, for to You I pray.
3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
In the morning, O LORD, You hear my voice; at daybreak I lay my plea before You and wait in expectation.
4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
For You are not a God who delights in wickedness; no evil can dwell with You.
5 Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú rẹ̀. Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
The boastful cannot stand in Your presence; You hate all workers of iniquity.
6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra.
You destroy those who tell lies; the LORD abhors the man of bloodshed and deceit.
7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀, èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀; ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
But I will enter Your house by the abundance of Your loving devotion; in reverence I will bow down toward Your holy temple.
8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi, mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
Lead me, O LORD, in Your righteousness because of my enemies; make straight Your way before me.
9 Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́; ọkàn wọn kún fún ìparun. Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀; pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
For not a word they speak can be trusted; destruction lies within them. Their throats are open graves; their tongues practice deceit.
10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run! Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn. Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
Declare them guilty, O God; let them fall by their own devices. Drive them out for their many transgressions, for they have rebelled against You.
11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀; jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí. Tan ààbò rẹ sórí wọn, àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
But let all who take refuge in You rejoice; let them ever shout for joy. May You shelter them, that those who love Your name may rejoice in You.
12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo; ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.
For surely You, O LORD, bless the righteous; You surround them with the shield of Your favor.

< Psalms 5 >