< Psalms 49 >

1 Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
למנצח לבני-קרח מזמור ב שמעו-זאת כל-העמים האזינו כל-ישבי חלד
2 Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
גם-בני אדם גם-בני-איש-- יחד עשיר ואביון
3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
פי ידבר חכמות והגות לבי תבונות
4 èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe, èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.
אטה למשל אזני אפתח בכנור חידתי
5 Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé? Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
למה אירא בימי רע-- עון עקבי יסובני
6 àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
הבטחים על-חילם וברב עשרם יתהללו
7 Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run.
אח--לא פדה יפדה איש לא-יתן לאלהים כפרו
8 Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
ויקר פדיון נפשם וחדל לעולם
9 ní ti kí ó máa wà títí ayé láìrí isà òkú.
ויחי-עוד לנצח לא יראה השחת
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
כי יראה חכמים ימותו-- יחד כסיל ובער יאבדו ועזבו לאחרים חילם
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé, ibùgbé wọn láti ìrandíran, wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.
קרבם בתימו לעולם-- משכנתם לדור ודר קראו בשמותם עלי אדמות
12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
ואדם ביקר בל-ילין נמשל כבהמות נדמו
13 Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. (Sela)
זה דרכם כסל למו ואחריהם בפיהם ירצו סלה
14 Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀. Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn. (Sheol h7585)
כצאן לשאול שתו-- מות ירעם וירדו בם ישרים לבקר--וצירם (וצורם) לבלות שאול מזבל לו (Sheol h7585)
15 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú, yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀. (Sheol h7585)
אך-אלהים--יפדה נפשי מיד-שאול כי יקחני סלה (Sheol h7585)
16 Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀. Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.
אל-תירא כי-יעשר איש כי-ירבה כבוד ביתו
17 Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú, ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú.
כי לא במותו יקח הכל לא-ירד אחריו כבודו
18 Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀. Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere.
כי-נפשו בחייו יברך ויודך כי-תיטיב לך
19 Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀ àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.
תבוא עד-דור אבותיו עד-נצח לא יראו-אור
20 Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
אדם ביקר ולא יבין נמשל כבהמות נדמו

< Psalms 49 >