< Psalms 46 >
1 Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin. Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
For the leader. Of the Korahites, on alamoth. A song. God is our refuge and strength, a very present help in trouble.
2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí, tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
So we have no fear, though earth should change, and the hills totter into the heart of the ocean.
3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. (Sela)
Let its waters roar and foam, let the mountains shake with the swelling thereof. On our side is the Lord of hosts, our sure defence is the God of Jacob. (Selah)
4 Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
A river there is, whose streams make glad God’s city, the home the Most High has hallowed.
5 Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
God is within her: she cannot be shaken. God helps her at the turn of the morning.
6 Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú, ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.
Nations roared, kingdoms tottered: he uttered his voice, earth melted away.
7 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.
On our side is the Lord of hosts, our sure defence is the God of Jacob.
8 Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
Come and see what the Lord has done, working appallingly in the earth.
9 O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.
He stills wars to the ends of the earth – breaking the bow, snapping the spear, burning the chariots in the fire.
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè, a ó gbé mi ga ní ayé.
‘Refrain; and know surely that I am God, high over the nations, high over the world.’
11 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa; Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.
On our side is the Lord of Hosts, our sure defence is the God of Jacob. (Selah)