< Psalms 45 >
1 Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó. Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.
For the Leader; upon Shoshannim; a Psalm of the sons of Korah. Maschil. A Song of loves. My heart overfloweth with a goodly matter; I say: 'My work is concerning a king'; my tongue is the pen of a ready writer.
2 Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ: a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè: nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.
Thou art fairer than the children of men; grace is poured upon thy lips; therefore God hath blessed thee for ever.
3 Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
Gird thy sword upon thy thigh, O mighty one, thy glory and thy majesty.
4 Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́; jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
And in thy majesty prosper, ride on, in behalf of truth and meekness and righteousness; and let thy right hand teach thee tremendous things.
5 Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
Thine arrows are sharp — the peoples fall under thee — they sink into the heart of the king's enemies.
6 Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ, ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
Thy throne given of God is for ever and ever; a sceptre of equity is the sceptre of thy kingdom.
7 Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, nípa fífi àmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
Thou hast loved righteousness, and hated wickedness; therefore God, thy God, hath anointed thee with the oil of gladness above thy fellows.
8 Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia; láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
Myrrh, and aloes, and cassia are all thy garments; out of ivory palaces stringed instruments have made thee glad.
9 Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró nínú wúrà Ofiri.
Kings' daughters are among thy favourites; at thy right hand doth stand the queen in gold of Ophir.
10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ.
'Hearken, O daughter, and consider, and incline thine ear; forget also thine own people, and thy father's house;
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi nítorí òun ni olúwa rẹ kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
So shall the king desire thy beauty; for he is thy lord; and do homage unto him.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
And, O daughter of Tyre, the richest of the people shall entreat thy favour with a gift.'
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀, iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
All glorious is the king's daughter within the palace; her raiment is of chequer work inwrought with gold.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá, àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
She shall be led unto the king on richly woven stuff; the virgins her companions in her train being brought unto thee.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn wọ́n sì wọ ààfin ọba.
They shall be led with gladness and rejoicing; they shall enter into the king's palace.
16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀ ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.
Instead of thy fathers shall be thy sons, whom thou shalt make princes in all the land.
17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo, nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.
I will make thy name to be remembered in all generations; therefore shall the peoples praise thee for ever and ever.