< Psalms 44 >

1 Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili. À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run; àwọn baba wa tí sọ fún wa ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
למנצח לבני קרח משכיל אלהים באזנינו שמענו אבותינו ספרו לנו פעל פעלת בימיהם בימי קדם׃
2 Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde, Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
אתה ידך גוים הורשת ותטעם תרע לאמים ותשלחם׃
3 Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
כי לא בחרבם ירשו ארץ וזרועם לא הושיעה למו כי ימינך וזרועך ואור פניך כי רציתם׃
4 Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
אתה הוא מלכי אלהים צוה ישועות יעקב׃
5 Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,
בך צרינו ננגח בשמך נבוס קמינו׃
6 èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi, idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
כי לא בקשתי אבטח וחרבי לא תושיעני׃
7 ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
כי הושעתנו מצרינו ומשנאינו הבישות׃
8 Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́, àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. (Sela)
באלהים הללנו כל היום ושמך לעולם נודה סלה׃
9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá, Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
אף זנחת ותכלימנו ולא תצא בצבאותינו׃
10 Ìwọ ti bá wa jà, ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa, àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa, wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
תשיבנו אחור מני צר ומשנאינו שסו למו׃
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn, Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
תתננו כצאן מאכל ובגוים זריתנו׃
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré, Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.
תמכר עמך בלא הון ולא רבית במחיריהם׃
13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
תשימנו חרפה לשכנינו לעג וקלס לסביבותינו׃
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
תשימנו משל בגוים מנוד ראש בל אמים׃
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́, ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
כל היום כלמתי נגדי ובשת פני כסתני׃
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.
מקול מחרף ומגדף מפני אויב ומתנקם׃
17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
כל זאת באתנו ולא שכחנוך ולא שקרנו בבריתך׃
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
לא נסוג אחור לבנו ותט אשרינו מני ארחך׃
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú, tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
כי דכיתנו במקום תנים ותכס עלינו בצלמות׃
20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
אם שכחנו שם אלהינו ונפרש כפינו לאל זר׃
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
הלא אלהים יחקר זאת כי הוא ידע תעלמות לב׃
22 Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.
כי עליך הרגנו כל היום נחשבנו כצאן טבחה׃
23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn? Dìde fúnra rẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
עורה למה תישן אדני הקיצה אל תזנח לנצח׃
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́ tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?
למה פניך תסתיר תשכח ענינו ולחצנו׃
25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku; ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
כי שחה לעפר נפשנו דבקה לארץ בטננו׃
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́; rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
קומה עזרתה לנו ופדנו למען חסדך׃

< Psalms 44 >