< Psalms 40 >

1 Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dúró de Olúwa; ó sì dẹtí sí mi, ó sì gbọ́ ẹkún mi.
לַמְנַצֵּחַ לְדָוִד מִזְמֽוֹר׃ קַוֺּה קִוִּיתִי יְהֹוָה וַיֵּט אֵלַי וַיִּשְׁמַע שַׁוְעָתִֽי׃
2 Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
וַיַּעֲלֵנִי ׀ מִבּוֹר שָׁאוֹן מִטִּיט הַיָּוֵן וַיָּקֶם עַל־סֶלַע רַגְלַי כּוֹנֵן אֲשֻׁרָֽי׃
3 Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
וַיִּתֵּן בְּפִי ׀ שִׁיר חָדָשׁ תְּהִלָּה לֵאלֹהֵינוּ יִרְאוּ רַבִּים וְיִירָאוּ וְיִבְטְחוּ בַּיהֹוָֽה׃
4 Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
אַשְֽׁרֵי הַגֶּבֶר אֲשֶׁר־שָׂם יְהֹוָה מִבְטַחוֹ וְֽלֹא־פָנָה אֶל־רְהָבִים וְשָׂטֵי כָזָֽב׃
5 Olúwa Ọlọ́run mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ti ṣe. Àwọn ohun tí ìwọ ti ṣètò sílẹ̀ fún wa; ni ẹnikẹ́ni kò le kà wọ́n fún ọ lẹ́sẹẹsẹ, tí èmi yóò sì sọ̀rọ̀ wọn, wọ́n ju ohun tí ènìyàn le è kà lọ.
רַבּוֹת עָשִׂיתָ ׀ אַתָּה ׀ יְהֹוָה אֱלֹהַי נִפְלְאֹתֶיךָ וּמַחְשְׁבֹתֶיךָ אֵלֵינוּ אֵין ׀ עֲרֹךְ אֵלֶיךָ אַגִּידָה וַאֲדַבֵּרָה עָצְמוּ מִסַּפֵּֽר׃
6 Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti ṣí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè.
זֶבַח וּמִנְחָה ׀ לֹֽא־חָפַצְתָּ אׇזְנַיִם כָּרִיתָ לִּי עוֹלָה וַחֲטָאָה לֹא שָׁאָֽלְתָּ׃
7 Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé.
אָז אָמַרְתִּי הִנֵּה־בָאתִי בִּמְגִלַּת־סֵפֶר כָּתוּב עָלָֽי׃
8 Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”
לַעֲשׂוֹת־רְצוֹנְךָ אֱלֹהַי חָפָצְתִּי וְתוֹרָתְךָ בְּתוֹךְ מֵעָֽי׃
9 Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà láàrín àwùjọ ńlá; wò ó, èmi kò pa ètè mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀, ìwọ Olúwa.
בִּשַּׂרְתִּי צֶדֶק ׀ בְּקָהָל רָב הִנֵּה שְׂפָתַי לֹא אֶכְלָא יְהֹוָה אַתָּה יָדָֽעְתָּ׃
10 Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi; èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ. Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.
צִדְקָתְךָ לֹֽא־כִסִּיתִי ׀ בְּתוֹךְ לִבִּי אֱמוּנָתְךָ וּתְשׁוּעָתְךָ אָמָרְתִּי לֹא־כִחַדְתִּי חַסְדְּךָ וַאֲמִתְּךָ לְקָהָל רָֽב׃
11 Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.
אַתָּה יְהֹוָה לֹֽא־תִכְלָא רַחֲמֶיךָ מִמֶּנִּי חַסְדְּךָ וַאֲמִתְּךָ תָּמִיד יִצְּרֽוּנִי׃
12 Nítorí pé àìníye ibi ni ó yí mi káàkiri, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi, títí tí èmi kò fi ríran mọ́; wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ, àti wí pé àyà mí ti kùnà.
כִּי אָפְפֽוּ־עָלַי ׀ רָעוֹת עַד־אֵין מִסְפָּר הִשִּׂיגוּנִי עֲוֺנֹתַי וְלֹא־יָכֹלְתִּי לִרְאוֹת עָצְמוּ מִשַּׂעֲרוֹת רֹאשִׁי וְלִבִּי עֲזָבָֽנִי׃
13 Jẹ́ kí ó wù ọ́, ìwọ Olúwa, láti gbà mí là; Olúwa, yára láti ràn mí lọ́wọ́.
רְצֵה יְהֹוָה לְהַצִּילֵנִי יְהֹוָה לְעֶזְרָתִי חֽוּשָׁה׃
14 Gbogbo àwọn wọ̀n-ọn-nì ni kí ojú kí ó tì kí wọn kí ó sì dààmú; àwọn tí ń wá ọkàn mi láti parun jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìn kí a sì dójútì wọ́n, àwọn tí ń wá ìpalára mi.
יֵבֹשׁוּ וְיַחְפְּרוּ ׀ יַחַד מְבַקְשֵׁי נַפְשִׁי לִסְפּוֹתָהּ יִסֹּגוּ אָחוֹר וְיִכָּלְמוּ חֲפֵצֵי רָעָתִֽי׃
15 Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Háà! Háà!” ó di ẹni à fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtìjú wọn.
יָשֹׁמּוּ עַל־עֵקֶב בׇּשְׁתָּם הָאֹמְרִים לִי הֶאָח ׀ הֶאָֽח׃
16 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ kí ó máa yọ̀ kí inú wọn sì máa dùn sí ọ; kí gbogbo àwọn tí ó sì fẹ́ ìgbàlà rẹ kí o máa wí nígbà gbogbo pé, “Gbígbéga ni Olúwa!”
יָשִׂישׂוּ וְיִשְׂמְחוּ ׀ בְּךָ כׇּֽל־מְבַקְשֶׁיךָ יֹאמְרוּ תָמִיד יִגְדַּל יְהֹוָה אֹהֲבֵי תְּשׁוּעָתֶֽךָ׃
17 Bí ó ṣe ti èmi ni, tálákà àti aláìní ni èmi, ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti ìgbàlà mi; má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́, ìwọ Ọlọ́run mi.
וַאֲנִי ׀ עָנִי וְאֶבְיוֹן אֲדֹנָי יַחֲשׇׁב ־ לִי עֶזְרָתִי וּמְפַלְטִי אַתָּה אֱלֹהַי אַל־תְּאַחַֽר׃

< Psalms 40 >