< Psalms 38 >

1 Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀. Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
מזמור לדוד להזכיר ב יהוה--אל-בקצפך תוכיחני ובחמתך תיסרני
2 Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
כי-חציך נחתו בי ותנחת עלי ידך
3 Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ; kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
אין-מתם בבשרי מפני זעמך אין-שלום בעצמי מפני חטאתי
4 Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀; wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.
כי עונתי עברו ראשי כמשא כבד יכבדו ממני
5 Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́ nítorí òmùgọ̀ mi.
הבאישו נמקו חבורתי מפני אולתי
6 Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
נעויתי שחתי עד-מאד כל-היום קדר הלכתי
7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.
כי-כסלי מלאו נקלה ואין מתם בבשרי
8 Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ; mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.
נפוגותי ונדכיתי עד-מאד שאגתי מנהמת לבי
9 Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sá pamọ́ fún ọ.
אדני נגדך כל-תאותי ואנחתי ממך לא-נסתרה
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀; bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
לבי סחרחר עזבני כחי ואור-עיני גם-הם אין אתי
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi, àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
אהבי ורעי--מנגד נגעי יעמדו וקרובי מרחק עמדו
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi; àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.
וינקשו מבקשי נפשי ודרשי רעתי דברו הוות ומרמות כל-היום יהגו
13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀; àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
ואני כחרש לא אשמע וכאלם לא יפתח-פיו
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀, àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
ואהי--כאיש אשר לא-שמע ואין בפיו תוכחות
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè; ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
כי-לך יהוה הוחלתי אתה תענה אדני אלהי
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí; nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”
כי-אמרתי פן-ישמחו-לי במוט רגלי עלי הגדילו
17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú, ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
כי-אני לצלע נכון ומכאובי נגדי תמיד
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi; àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
כי-עוני אגיד אדאג מחטאתי
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
ואיבי חיים עצמו ורבו שנאי שקר
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi àwọn ni ọ̀tá mi nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.
ומשלמי רעה תחת טובה-- ישטנוני תחת רדופי- (רדפי-) טוב
21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa! Ọlọ́run mi, má ṣe jìnnà sí mi.
אל-תעזבני יהוה אלהי אל-תרחק ממני
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́, Olúwa, Olùgbàlà mi.
חושה לעזרתי אדני תשועתי

< Psalms 38 >