< Psalms 36 >

1 Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa. Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé, ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.
למנצח לעבד יהוה לדוד נאם פשע לרשע בקרב לבי אין פחד אלהים לנגד עיניו׃
2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
כי החליק אליו בעיניו למצא עונו לשנא׃
3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn; wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀.
דברי פיו און ומרמה חדל להשכיל להיטיב׃
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn: wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
און יחשב על משכבו יתיצב על דרך לא טוב רע לא ימאס׃
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run, òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
יהוה בהשמים חסדך אמונתך עד שחקים׃
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run, àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá; ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
צדקתך כהררי אל משפטך תהום רבה אדם ובהמה תושיע יהוה׃
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
מה יקר חסדך אלהים ובני אדם בצל כנפיך יחסיון׃
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
ירוין מדשן ביתך ונחל עדניך תשקם׃
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
כי עמך מקור חיים באורך נראה אור׃
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
משך חסדך לידעיך וצדקתך לישרי לב׃
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi, kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
אל תבואני רגל גאוה ויד רשעים אל תנדני׃
12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí: a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!
שם נפלו פעלי און דחו ולא יכלו קום׃

< Psalms 36 >