< Psalms 33 >
1 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo; ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
Rejoice in the LORD, O righteous ones; it is fitting for the upright to praise Him.
2 Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù; ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
Praise the LORD with the harp; make music to Him with ten strings.
3 Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.
Sing to Him a new song; play skillfully with a shout of joy.
4 Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
For the word of the LORD is upright, and all His work is trustworthy.
5 Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.
The LORD loves righteousness and justice; the earth is full of His loving devotion.
6 Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
By the word of the LORD the heavens were made, and all the stars by the breath of His mouth.
7 Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
He piles up the waters of the sea; He puts the depths into storehouses.
8 Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
Let all the earth fear the LORD; let all the people of the world revere Him.
9 Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.
For He spoke, and it came to be; He commanded, and it stood firm.
10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
The LORD frustrates the plans of the nations; He thwarts the devices of the peoples.
11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.
The counsel of the LORD stands forever, the purposes of His heart to all generations.
12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
Blessed is the nation whose God is the LORD, the people He has chosen as His inheritance!
13 Olúwa wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
The LORD looks down from heaven; He sees all the sons of men.
14 Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
From His dwelling place He gazes on all who inhabit the earth.
15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsi ìṣe wọn.
He shapes the hearts of each; He considers all their works.
16 A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.
No king is saved by his vast army; no warrior is delivered by his great strength.
17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
A horse is a vain hope for salvation; even its great strength cannot save.
18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.
Surely the eyes of the LORD are on those who fear Him, on those whose hope is in His loving devotion
19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.
to deliver them from death and keep them alive in famine.
20 Ọkàn wa dúró de Olúwa; òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.
Our soul waits for the LORD; He is our help and our shield.
21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀, nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.
For our hearts rejoice in Him, since we trust in His holy name.
22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.
May Your loving devotion rest on us, O LORD, as we put our hope in You.