< Psalms 3 >
1 Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu. Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
A Psalm of David, when he fled from his son Absalom. O LORD, how my foes have increased! How many rise up against me!
2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò nígbà á là.” (Sela)
Many say of me, “God will not deliver him.”
3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
But You, O LORD, are a shield around me, my glory, and the One who lifts my head.
4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. (Sela)
To the LORD I cry aloud, and He answers me from His holy mountain.
5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
I lie down and sleep; I wake again, for the LORD sustains me.
6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
I will not fear the myriads set against me on every side.
7 Dìde, Olúwa! Gbà mí, Ọlọ́run mi! Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n; kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
Arise, O LORD! Save me, O my God! Strike all my enemies on the jaw; break the teeth of the wicked.
8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá. Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. (Sela)
Salvation belongs to the LORD; may Your blessing be on Your people.