< Psalms 25 >
1 Ti Dafidi. Olúwa, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
[A Psalm] of David. Unto thee, O LORD, do I lift up my soul.
2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
O my God, I trust in thee: let me not be ashamed, let not mine enemies triumph over me.
3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì.
Yea, let none that wait on thee be ashamed: let them be ashamed which transgress without cause.
4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa, kọ mi ní ipa tìrẹ;
Shew me thy ways, O LORD; teach me thy paths.
5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
Lead me in thy truth, and teach me: for thou [art] the God of my salvation; on thee do I wait all the day.
6 Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá, torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́.
Remember, O LORD, thy tender mercies and thy lovingkindnesses; for they [have been] ever of old.
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi tàbí ìrékọjá mi; gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
Remember not the sins of my youth, nor my transgressions: according to thy mercy remember thou me for thy goodness’ sake, O LORD.
8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa: nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
Good and upright [is] the LORD: therefore will he teach sinners in the way.
9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára, ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
The meek will he guide in judgment: and the meek will he teach his way.
10 Gbogbo ipa ọ̀nà Olúwa ni ìfẹ́ àti òdodo tí ó dúró ṣinṣin, fún àwọn tí ó pa májẹ̀mú àti ẹ̀rí rẹ̀ mọ́.
All the paths of the LORD [are] mercy and truth unto such as keep his covenant and his testimonies.
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
For thy name’s sake, O LORD, pardon mine iniquity; for it [is] great.
12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa? Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
What man [is] he that feareth the LORD? him shall he teach in the way [that] he shall choose.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
His soul shall dwell at ease; and his seed shall inherit the earth.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
The secret of the LORD [is] with them that fear him; and he will shew them his covenant.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
Mine eyes [are] ever toward the LORD; for he shall pluck my feet out of the net.
16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
Turn thee unto me, and have mercy upon me; for I [am] desolate and afflicted.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
The troubles of my heart are enlarged: [O] bring thou me out of my distresses.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
Look upon mine affliction and my pain; and forgive all my sins.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
Consider mine enemies; for they are many; and they hate me with cruel hatred.
20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
O keep my soul, and deliver me: let me not be ashamed; for I put my trust in thee.
21 Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́.
Let integrity and uprightness preserve me; for I wait on thee.
22 Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!
Redeem Israel, O God, out of all his troubles.