< Psalms 24 >

1 Ti Dafidi. Saamu. Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
The earth is the LORD’s, and the fullness thereof; the world, and they that dwell therein.
2 nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkun ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.
For he has founded it on the seas, and established it on the floods.
3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
Who shall ascend into the hill of the LORD? or who shall stand in his holy place?
4 Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.
He that has clean hands, and a pure heart; who has not lifted up his soul to vanity, nor sworn deceitfully.
5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
He shall receive the blessing from the LORD, and righteousness from the God of his salvation.
6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. (Sela)
This is the generation of them that seek him, that seek your face, O Jacob. (Selah)
7 Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé.
Lift up your heads, O you gates; and be you lift up, you everlasting doors; and the King of glory shall come in.
8 Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
Who is this King of glory? The LORD strong and mighty, the LORD mighty in battle.
9 Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá.
Lift up your heads, O you gates; even lift them up, you everlasting doors; and the King of glory shall come in.
10 Ta ni Ọba ògo náà? Olúwa àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. (Sela)
Who is this King of glory? The LORD of hosts, he is the King of glory. (Selah)

< Psalms 24 >