< Psalms 22 >
1 Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi?
For the end, concerning the morning aid, a Psalm of David. O God, my God, attend to me: why have you forsaken me? the account of my transgressions is far from my salvation.
2 Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́.
O my God, I will cry to you by day, but you will not hear: and by night, and [it shall] not [be accounted] for folly to me.
3 Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.
But you, the praise of Israel, dwell in a sanctuary.
4 Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
Our fathers hoped in you; they hoped, and you did deliver them.
5 Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.
They cried to you, and were saved: they hoped in you, and were not ashamed.
6 Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn; mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn.
But I am a worm, and not a man; a reproach of men, and scorn of the people.
7 Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà; wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
All that saw me mocked me: they spoke with [their] lips, they shook the head, [saying],
8 “Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa; jẹ́ kí Olúwa gbà á là. Jẹ́ kí ó gbà á là, nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”
He hoped in the Lord: let him deliver him, let him save him, because he takes pleasure in him.
9 Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú; ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
For you are he that drew me out of the womb; my hope from my mother's breasts.
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá, nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.
I was cast on you from the womb: you are my God from my mother's belly.
11 Má ṣe jìnnà sí mi, nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.
Stand not aloof from me; for affliction is near; for there is no helper.
12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká; àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
Many bullocks have compassed me: fat bulls have beset me round.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù.
They have opened their mouth against me, as a ravening and roaring lion.
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀. Ọkàn mi sì dàbí i ìda; tí ó yọ́ láàrín inú mi.
I am poured out like water, and all my bones are loosened: my heart in the midst of my belly is become like melting wax.
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi; ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú. ()
My strength is dried up, like a potsherd; and my tongue is glued to my throat; and you have brought me down to the dust of death.
16 Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.
For many dogs have compassed me: the assembly of the wicked doers has beset me round: they pierced my hands and my feet.
17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi; àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
They counted all my bones; and they observed and looked upon me.
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.
They parted my garments [amongst] themselves, and cast lots upon my raiment.
19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi. Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
But you, O Lord, remove not my help afar off: be ready for mine aid.
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
Deliver my soul from the sword; my only-begotten one from the power of the dog.
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún; kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.
Save me from the lion's mouth; and [regard] my lowliness from the horns of the unicorns.
22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi; nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
I will declare your name to my brethren: in the midst of the church will I sing praise to you.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín! Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un! Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
You that fear the Lord, praise him; all you seed of Jacob, glorify him: let all the seed of Israel fear him.
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.
For he has not despised nor been angry at the supplication of the poor; nor turned away his face from me; but when I cried to him, he heard me.
25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá; ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
My praise is of you in the great congregation: I will pay my vows before them that fear him.
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó; àwọn tí n wá Olúwa yóò yin jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!
The poor shall eat and be satisfied; and they shall praise the Lord that seek him: their heart shall live for ever.
27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí wọn yóò sì yípadà sí Olúwa, àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
All the ends of the earth shall remember and turn to the Lord: and all the kindred of the nations shall worship before him.
28 nítorí ìjọba ni ti Olúwa. Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
For the kingdom is the Lord's; and he is the governor of the nations.
29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn; gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
All the fat ones of the earth have eaten and worshipped: all that go down to the earth shall fall down before him: my soul also lives to him.
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín; a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa.
And my seed shall serve him: the generation that is coming shall be reported to the Lord.
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí, wí pé, òun ni ó ṣe èyí.
And they shall report his righteousness to the people that shall be born, whom the Lord has made.