< Psalms 18 >
1 Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé. Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
Начальнику хора. Раба Господня Давида, который произнес слова песни сей к Господу, когда Господь избавил его от рук всех врагов его и от руки Саула. И он сказал: Возлюблю тебя, Господи, крепость моя!
2 Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
Господь - твердыня моя и прибежище мое, Избавитель мой, Бог мой, скала моя; на Него я уповаю; щит мой, рог спасения моего и убежище мое.
3 Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
Призову достопоклоняемого Господа и от врагов моих спасусь.
4 Ìrora ikú yí mi kà, àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
Объяли меня муки смертные, и потоки беззакония устрашили меня;
5 Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. (Sheol )
цепи ада облегли меня, и сети смерти опутали меня. (Sheol )
6 Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa; mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
В тесноте моей я призвал Господа и к Богу моему воззвал. И Он услышал от чертога Своего голос мой, и вопль мой дошел до слуха Его.
7 Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
Потряслась и всколебалась земля, дрогнули и подвиглись основания гор, ибо разгневался Бог;
8 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
поднялся дым от гнева Его и из уст Его огонь поядающий; горячие угли сыпались от Него.
9 Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
Наклонил Он небеса и сошел, - и мрак под ногами Его.
10 Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
И воссел на херувимов и полетел, и понесся на крыльях ветра.
11 Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
И мрак сделал покровом Своим, сению вокруг Себя мрак вод, облаков воздушных.
12 Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
От блистания пред Ним бежали облака Его, град и угли огненные.
13 Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá; Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
Возгремел на небесах Господь, и Всевышний дал глас Свой, град и угли огненные.
14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
Пустил стрелы Свои и рассеял их, множество молний, и рассыпал их.
15 A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn, a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé nípa ìbáwí rẹ, Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
И явились источники вод, и открылись основания вселенной от грозного гласа Твоего, Господи, от дуновения духа гнева Твоего.
16 Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú; Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
Он простер руку с высоты и взял меня, и извлек меня из вод многих;
17 Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
избавил меня от врага моего сильного и от ненавидящих меня, которые были сильнее меня.
18 Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi; ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.
Они восстали на меня в день бедствия моего, но Господь был мне опорою.
19 Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá; Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
Он вывел меня на пространное место и избавил меня, ибо Он благоволит ко мне.
20 Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.
Воздал мне Господь по правде моей, по чистоте рук моих вознаградил меня,
21 Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́; èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
ибо я хранил пути Господни и не был нечестивым пред Богом моим;
22 Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
ибо все заповеди Его предо мною, и от уставов Его я не отступал.
23 Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀; mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
Я был непорочен пред Ним и остерегался, чтобы не согрешить мне;
24 Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
и воздал мне Господь по правде моей, по чистоте рук моих пред очами Его.
25 Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́, sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
С милостивым Ты поступаешь милостиво, с мужем искренним - искренно,
26 sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́, ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
с чистым - чисто, а с лукавым - по лукавству его,
27 O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
ибо Ты людей угнетенных спасаешь, а очи надменные унижаешь.
28 Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
Ты возжигаешь светильник мой, Господи; Бог мой просвещает тьму мою.
29 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ; pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
С Тобою я поражаю войско, с Богом моим восхожу на стену.
30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
Бог! - Непорочен путь Его, чисто слово Господа; щит Он для всех, уповающих на Него.
31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa? Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
Ибо кто Бог, кроме Господа, и кто защита, кроме Бога нашего?
32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè ó sì mú ọ̀nà mi pé.
Бог препоясывает меня силою и устрояет мне верный путь;
33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
делает ноги мои, как оленьи, и на высотах моих поставляет меня;
34 Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà; apá mi lè tẹ ọrùn idẹ.
научает руки мои брани, и мышцы мои сокрушают медный лук.
35 Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró; àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
Ты дал мне щит спасения Твоего, и десница Твоя поддерживает меня, и милость Твоя возвеличивает меня.
36 Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi, kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
Ты расширяешь шаг мой подо мною, и не колеблются ноги мои.
37 Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
Я преследую врагов моих и настигаю их, и не возвращаюсь, доколе не истреблю их;
38 Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde; wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
поражаю их, и они не могут встать, падают под ноги мои,
39 Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
ибо Ты препоясал меня силою для войны и низложил под ноги мои восставших на меня;
40 Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
Ты обратил ко мне тыл врагов моих, и я истребляю ненавидящих меня:
41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n, àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
они вопиют, но нет спасающего; ко Господу, - но Он не внемлет им;
42 Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́; mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
я рассеваю их, как прах пред лицем ветра, как уличную грязь попираю их.
43 Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
Ты избавил меня от мятежа народа, поставил меня главою иноплеменников; народ, которого я не знал, служит мне;
44 ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́; àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
по одному слуху о мне повинуются мне; иноплеменники ласкательствуют предо мною;
45 Àyà yóò pá àlejò; wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
иноплеменники бледнеют и трепещут в укреплениях своих.
46 Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi! Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
Жив Господь и благословен защитник мой! Да будет превознесен Бог спасения моего,
47 Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi, tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
Бог, мстящий за меня и покоряющий мне народы,
48 tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí. Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ; lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
и избавляющий меня от врагов моих! Ты вознес меня над восстающими против меня и от человека жестокого избавил меня.
49 Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa; èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
За то буду славить Тебя, Господи, между иноплеменниками и буду петь имени Твоему,
50 Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá; ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.
величественно спасающий царя и творящий милость помазаннику Твоему Давиду и потомству его во веки.