< Psalms 17 >

1 Àdúrà ti Dafidi. Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi; fi etí sí igbe mi. Tẹ́tí sí àdúrà mi tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.
“A psalm of David.” Hear the righteous cause, O LORD! Attend to my cry; Give ear to my prayer from lips without deceit!
2 Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ; kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.
May my sentence come forth from thy presence; May thine eyes behold uprightness!
3 Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi, ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé, ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.
Provest thou my heart, visitest thou me in the night, Triest thou me like gold, thou shalt find nothing!
4 Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, èmi ti pa ara mi mọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.
My thoughts do not vary from my lips. As to the deeds of men, Through the word of thy lips I have kept me from the paths of the destroyer.
5 Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ; ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.
Support my steps in thy paths, That my feet may not slip!
6 Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
I call upon thee, O God! for thou wilt hear me; Incline thine ear to me, and listen to my prayer!
7 Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
Show forth thy loving-kindness, O thou that savest by thy right hand Them that seek refuge in thee from their adversaries!
8 Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,
Guard me as the apple of the eye; Hide me under the shadow of thy wings
9 lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.
From the wicked who assault me, From my deadly enemies who compass me about!
10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́, wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
They shut up their hard heart; With their mouth they speak haughtily.
11 Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká, pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀.
They encompass us in all our steps; They fix their eyes upon us, that they may cast us on the ground.
12 Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ, àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.
They are like a lion, eager for his prey; Like a young lion, lurking in secret places.
13 Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.
Arise, O LORD! disappoint them, cast them down! Deliver me from the wicked by thy sword,
14 Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí. Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.
From men, by thy hand, O LORD! from men of the world, Whose portion is in life; whom thou loadest with thy treasure; Whose children have enough, and leave their superfluity to their children.
15 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.
But I through righteousness shall see thy face; I shall be satisfied with the revival of thy countenance.

< Psalms 17 >