< Psalms 15 >

1 Saamu ti Dafidi. Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?
Davut'un mezmuru Ya RAB, çadırına kim konuk olabilir? Kutsal dağında kim oturabilir?
2 Ẹni tí ń rìn déédé tí ó sì ń sọ òtítọ́, láti inú ọkàn rẹ̀;
Kusursuz yaşam süren, adil davranan, Yürekten gerçeği söyleyen.
3 tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀ tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
İftira etmez, Dostuna zarar vermez, Komşusuna kara çalmaz böylesi.
4 ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀ àní tí kò sì yípadà,
Aşağılık insanları hor görür, Ama RAB'den korkanlara saygı duyar. Kendi zararına ant içse bile, dönmez andından.
5 tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí ni a kì yóò mì láéláé.
Parasını faize vermez, Suçsuza karşı rüşvet almaz. Böyle yaşayan asla sarsılmayacak.

< Psalms 15 >