< Psalms 148 >

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá, ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
הללו יה הללו את יהוה מן השמים הללוהו במרומים׃
2 Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀, ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.
הללוהו כל מלאכיו הללוהו כל צבאו׃
3 Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá. Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
הללוהו שמש וירח הללוהו כל כוכבי אור׃
4 Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.
הללוהו שמי השמים והמים אשר מעל השמים׃
5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
יהללו את שם יהוה כי הוא צוה ונבראו׃
6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.
ויעמידם לעד לעולם חק נתן ולא יעבור׃
7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú òkun,
הללו את יהוה מן הארץ תנינים וכל תהמות׃
8 mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu, ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,
אש וברד שלג וקיטור רוח סערה עשה דברו׃
9 òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké, igi eléso àti gbogbo igi kedari,
ההרים וכל גבעות עץ פרי וכל ארזים׃
10 àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́,
החיה וכל בהמה רמש וצפור כנף׃
11 àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
מלכי ארץ וכל לאמים שרים וכל שפטי ארץ׃
12 ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.
בחורים וגם בתולות זקנים עם נערים׃
13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
יהללו את שם יהוה כי נשגב שמו לבדו הודו על ארץ ושמים׃
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
וירם קרן לעמו תהלה לכל חסידיו לבני ישראל עם קרבו הללו יה׃

< Psalms 148 >