< Psalms 147 >
1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa, ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
Praise the LORD, for it is good to sing praises to our God; for it is pleasant and fitting to praise him.
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu; Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
The LORD builds up Jerusalem. He gathers together the outcasts of Israel.
3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
He heals the broken in heart, and binds up their wounds.
4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.
He counts the number of the stars. He calls them all by their names.
5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
Great is our Lord, and mighty in power. His understanding is infinite.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
The LORD upholds the humble. He brings the wicked down to the ground.
7 Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
Sing to the LORD with thanksgiving. Sing praises on the harp to our God,
8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀ ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
who covers the sky with clouds, who prepares rain for the earth, who makes grass grow on the mountains.
9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
He provides food for the livestock, and for the young ravens when they call.
10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin, bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
He does not delight in the strength of the horse. He takes no pleasure in the legs of a man.
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
The LORD takes pleasure in those who fear him, in those who hope in his loving kindness.
12 Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu; yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.
Praise the LORD, Jerusalem! Praise your God, Zion!
13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára, Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
For he has strengthened the bars of your gates. He has blessed your children within you.
14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.
He makes peace in your borders. He fills you with the finest of the wheat.
15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
He sends out his commandment to the earth. His word runs very swiftly.
16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
He gives snow like wool, and scatters frost like ashes.
17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
He hurls down his hail like pebbles. Who can stand before his cold?
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́ ó sì mú odò rẹ̀ sàn.
He sends out his word, and melts them. He causes his wind to blow, and the waters flow.
19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli.
He shows his word to Jacob, his statutes and his ordinances to Israel.
20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀ wọn ko mọ òfin rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
He has not done this for just any nation. They do not know his ordinances. Praise the LORD!