< Psalms 146 >

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Praise the LORD! Praise the LORD, my soul.
2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi, èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
While I live, I will praise the LORD. I will sing praises to my God as long as I exist.
3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé, àní, ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
Do not put your trust in princes, in a son of man in whom there is no help.
4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.
His spirit departs, and he returns to the earth. In that very day, his thoughts perish.
5 Ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
Happy is he who has the God of Jacob for his help, whose hope is in the LORD, his God,
6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
who made heaven and earth, the sea, and all that is in them; who keeps truth forever;
7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára, tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa, Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀,
who executes justice for the oppressed; who gives food to the hungry. The LORD frees the prisoners.
8 Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran, Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga, Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.
The LORD opens the eyes of the blind. The LORD raises up those who are bowed down. The LORD loves the righteous.
9 Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
The LORD preserves the foreigners. He upholds the fatherless and widow, but he turns the way of the wicked upside down.
10 Olúwa jẹ ọba títí láé; Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
The LORD will reign forever; your God, O Zion, to all generations. Praise the LORD!

< Psalms 146 >