< Psalms 145 >
1 Saamu ìyìn. Ti Dafidi. Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi; èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé.
A Psalm of praise. Of David. I will extol thee, my God, O King, and I will bless thy name for ever and ever.
2 Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́ èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.
Every day will I bless thee, and I will praise thy name for ever and ever.
3 Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀: kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
Great is Jehovah, and exceedingly to be praised; and his greatness is unsearchable.
4 Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn; wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ.
One generation shall laud thy works to another, and shall declare thy mighty acts.
5 Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
I will speak of the glorious splendour of thy majesty, and of thy wondrous works.
6 Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
And they shall tell of the might of thy terrible acts; and thy great deeds will I declare.
7 Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.
They shall abundantly utter the memory of thy great goodness, and shall sing aloud of thy righteousness.
8 Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.
Jehovah is gracious and merciful; slow to anger, and of great loving-kindness.
9 Olúwa dára sí ẹni gbogbo; ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
Jehovah is good to all; and his tender mercies are over all his works.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni yóò máa yìn ọ́ Olúwa; àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
All thy works shall praise thee, Jehovah, and thy saints shall bless thee.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
They shall tell of the glory of thy kingdom, and speak of thy power;
12 kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀ àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
To make known to the children of men his mighty acts, and the glorious splendour of his kingdom.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni, àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
Thy kingdom is a kingdom of all ages, and thy dominion is throughout all generations.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
Jehovah upholdeth all that fall, and raiseth up all that are bowed down.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́, ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ.
The eyes of all wait upon thee; and thou givest them their food in its season.
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
Thou openest thy hand, and satisfiest the desire of every living thing.
17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
Jehovah is righteous in all his ways, and kind in all his works.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
Jehovah is nigh unto all that call upon him, unto all that call upon him in truth.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ; ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
He fulfilleth the desire of them that fear him; he heareth their cry, and saveth them.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni búburú ní yóò parun.
Jehovah keepeth all that love him, and all the wicked will he destroy.
21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa. Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.
My mouth shall speak the praise of Jehovah; and let all flesh bless his holy name for ever and ever.