< Psalms 144 >
1 Ti Dafidi. Ìyìn sí Olúwa àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, àti ìka mi fún ìjà.
Of David. Blessed be the LORD, my Rock, who trains my hands for war, my fingers for battle.
2 Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi, ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.
He is my steadfast love and my fortress, my stronghold and my deliverer. He is my shield, in whom I take refuge, who subdues peoples under me.
3 Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un, tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
O LORD, what is man, that You regard him, the son of man that You think of him?
4 Ènìyàn rí bí èmi; ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.
Man is like a breath; his days are like a passing shadow.
5 Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀; tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
Part Your heavens, O LORD, and come down; touch the mountains, that they may smoke.
6 Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká; ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
Flash forth Your lightning and scatter them; shoot Your arrows and rout them.
7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga; gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò nínú omi ńlá: kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
Reach down from on high; set me free and rescue me from the deep waters, from the grasp of foreigners,
8 Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.
whose mouths speak falsehood, whose right hands are deceitful.
9 Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ Ọlọ́run; lára ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá èmi yóò kọ orin sí ọ.
I will sing to You a new song, O God; on a harp of ten strings I will make music to You—
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba, ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára. Lọ́wọ́ pípanirun.
to Him who gives victory to kings, who frees His servant David from the deadly sword.
11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
Set me free and rescue me from the grasp of foreigners, whose mouths speak falsehood, whose right hands are deceitful.
12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
Then our sons will be like plants nurtured in their youth, our daughters like corner pillars carved to adorn a palace.
13 Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
Our storehouses will be full, supplying all manner of produce; our flocks will bring forth thousands, tens of thousands in our fields.
14 àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
Our oxen will bear great loads. There will be no breach in the walls, no going into captivity, and no cry of lament in our streets.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà, tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
Blessed are the people of whom this is so; blessed are the people whose God is the LORD.