< Psalms 143 >

1 Saamu ti Dafidi. Olúwa gbọ́ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.
מזמור לדוד יהוה שמע תפלתי האזינה אל תחנוני באמנתך ענני בצדקתך׃
2 Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.
ואל תבוא במשפט את עבדך כי לא יצדק לפניך כל חי׃
3 Ọ̀tá ń lépa mi, ó fún mi pamọ́ ilẹ̀; ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.
כי רדף אויב נפשי דכא לארץ חיתי הושיבני במחשכים כמתי עולם׃
4 Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi; ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.
ותתעטף עלי רוחי בתוכי ישתומם לבי׃
5 Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.
זכרתי ימים מקדם הגיתי בכל פעלך במעשה ידיך אשוחח׃
6 Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. (Sela)
פרשתי ידי אליך נפשי כארץ עיפה לך סלה׃
7 Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò.
מהר ענני יהוה כלתה רוחי אל תסתר פניך ממני ונמשלתי עם ירדי בור׃
8 Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀: nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí, nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.
השמיעני בבקר חסדך כי בך בטחתי הודיעני דרך זו אלך כי אליך נשאתי נפשי׃
9 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa, nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.
הצילני מאיבי יהוה אליך כסתי׃
10 Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára darí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
למדני לעשות רצונך כי אתה אלוהי רוחך טובה תנחני בארץ מישור׃
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè; nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.
למען שמך יהוה תחיני בצדקתך תוציא מצרה נפשי׃
12 Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò, run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára, nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.
ובחסדך תצמית איבי והאבדת כל צררי נפשי כי אני עבדך׃

< Psalms 143 >