< Psalms 142 >

1 Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà. Èmi kígbe sókè sí Olúwa; èmi gbé ohùn mi sókè sí Olúwa fún àánú.
A Maskil of David, when he was in the cave. A prayer. I cry aloud to the LORD; I lift my voice to the LORD for mercy.
2 Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.
I pour out my complaint before Him; I reveal my trouble to Him.
3 Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀.
Although my spirit grows faint within me, You know my way. Along the path I travel they have hidden a snare for me.
4 Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi èmi kò ní ààbò; kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi.
Look to my right and see; no one attends to me. There is no refuge for me; no one cares for my soul.
5 Èmi kígbe sí ọ, Olúwa: èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
I cry to You, O LORD: “You are my refuge, my portion in the land of the living.”
6 Fi etí sí igbe mi, nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi, nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ.
Listen to my cry, for I am brought quite low. Rescue me from my pursuers, for they are too strong for me.
7 Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú, kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
Free my soul from prison, that I may praise Your name. The righteous will gather around me because of Your goodness to me.

< Psalms 142 >