< Psalms 141 >

1 Saamu ti Dafidi. Olúwa, èmi ké pè ọ́; yára wá sí ọ̀dọ̀ mi. Gbọ́ ohùn mi, nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
大卫的诗。 耶和华啊,我曾求告你, 求你快快临到我这里! 我求告你的时候, 愿你留心听我的声音!
2 Jẹ́ kí àdúrà mi ó wá sí iwájú rẹ bí ẹbọ tùràrí àti ìgbé ọwọ́ mi si òkè rí bí ẹbọ àṣálẹ́.
愿我的祷告如香陈列在你面前! 愿我举手祈求,如献晚祭!
3 Fi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ẹnu mi, Olúwa: kí o sì máa pa ìlẹ̀kùn ètè mi mọ́.
耶和华啊,求你禁止我的口, 把守我的嘴!
4 Má ṣe jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ohun tí ń ṣe ibi, láti máa bá àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ búburú má sì ṣe jẹ́ kí èmi jẹ àdídùn wọn.
求你不叫我的心偏向邪恶, 以致我和作孽的人同行恶事; 也不叫我吃他们的美食。
5 Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́: jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi. Tí kì yóò fọ́ mi ní orí. Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.
任凭义人击打我,这算为仁慈; 任凭他责备我,这算为头上的膏油; 我的头不要躲闪。 正在他们行恶的时候,我仍要祈祷。
6 A ó ju àwọn alákòóso sílẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ òkúta, àwọn ẹni búburú yóò kọ pé àwọn ọ̀rọ̀ mi dùn.
他们的审判官被扔在岩下; 众人要听我的话,因为这话甘甜。
7 Wọn yóò wí pé, “Bí ẹni tí ó la aporo sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni egungun wa tànkálẹ̀ ní ẹnu isà òkú.” (Sheol h7585)
我们的骨头散在墓旁, 好像人耕田、刨地的土块。 (Sheol h7585)
8 Ṣùgbọ́n ojú mi ń bẹ lára rẹ, Olúwa Olódùmarè; nínú rẹ̀ ni èmi ti rí ààbò, má ṣe fà mi fún ikú.
主—耶和华啊,我的眼目仰望你; 我投靠你,求你不要将我撇得孤苦!
9 Pa mí mọ́ kúrò nínú okùn tí wọn ti dẹ sílẹ̀ fún mi, kúrò nínú ìkẹ́kùn àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
求你保护我脱离恶人为我设的网罗 和作孽之人的圈套!
10 Jẹ́ kí àwọn ẹni búburú ṣubú sínú àwọ̀n ara wọn, nígbà tí èmi bá kọjá lọ láìléwu.
愿恶人落在自己的网里, 我却得以逃脱。

< Psalms 141 >