< Psalms 140 >
1 Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,
[For the Chief Musician. A Psalm by David.] Deliver me, YHWH, from the evil man. Preserve me from the violent man;
2 ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn; nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
those who devise mischief in their hearts. They continually gather themselves together for war.
3 Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
They have sharpened their tongues like a serpent. Viper's poison is under their lips. (Selah)
4 Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú; yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.
YHWH, keep me from the hands of the wicked. Preserve me from the violent men who have determined to trip my feet.
5 Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn: wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà; wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.
The proud have hidden a snare for me, they have spread the cords of a net by the path. They have set traps for me. (Selah)
6 Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi; Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
I said to YHWH, "You are my God." Listen to the cry of my petitions, YHWH.
7 Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi, ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
YHWH, the strength of my salvation, you shield my head on the day of battle.
8 Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un; má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́; kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. (Sela)
YHWH, do not grant the desires of the wicked. Do not let their evil plans succeed, or they will become proud. (Selah)
9 Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni, jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
As for the head of those who surround me, let the mischief of their own lips cover them.
10 A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára, Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná, sínú ọ̀gbun omi jíjìn, kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
Let burning coals fall on them. Let them be thrown into the fire, into miry pits, from where they never rise.
11 Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé; ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
An evil speaker won't be established in the earth. Evil will hunt the violent man to overthrow him.
12 Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.
I know that YHWH will maintain the cause of the afflicted, and justice for the needy.
13 Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ; àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.
Surely the righteous will give thanks to your name. The upright will dwell in your presence.