< Psalms 14 >

1 Fún adarí orin. Ti Dafidi. Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Ko sí Ọlọ́run.” Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú; kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere. 2 Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run. 3 Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́; kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. 4 Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀? Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun; wọn kò sì ké pe Olúwa? 5 Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù, nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo. 6 Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú, ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn. 7 Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá! Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

< Psalms 14 >