< Psalms 139 >

1 Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Olúwa, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.
למנצח לדוד מזמור יהוה חקרתני ותדע
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
אתה ידעת שבתי וקומי בנתה לרעי מרחוק
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
ארחי ורבעי זרית וכל-דרכי הסכנתה
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
כי אין מלה בלשוני הן יהוה ידעת כלה
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
אחור וקדם צרתני ותשת עלי כפכה
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
פלאיה (פליאה) דעת ממני נשגבה לא-אוכל לה
7 Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
אנה אלך מרוחך ואנה מפניך אברח
8 Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Sheol h7585)
אם אסק שמים שם אתה ואציעה שאול הנך (Sheol h7585)
9 Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun,
אשא כנפי-שחר אשכנה באחרית ים
10 àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
גם-שם ידך תנחני ותאחזני ימינך
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
ואמר אך-חשך ישופני ולילה אור בעדני
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.
גם-חשך לא-יחשיך ממך ולילה כיום יאיר-- כחשיכה כאורה
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
כי-אתה קנית כליתי תסכני בבטן אמי
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.
אודך-- על כי נוראות נפליתי נפלאים מעשיך ונפשי ידעת מאד
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀. Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
לא-נכחד עצמי ממך אשר-עשיתי בסתר רקמתי בתחתיות ארץ
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé, àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
גלמי ראו עיניך ועל-ספרך כלם יכתבו ימים יצרו ולא (ולו) אחד בהם
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó!
ולי--מה-יקרו רעיך אל מה עצמו ראשיהם
18 Èmi ìbá kà wọ́n, wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye: nígbà tí mo bá jí, èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
אספרם מחול ירבון הקיצתי ועודי עמך
19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́; nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
אם-תקטל אלוה רשע ואנשי דמים סורו מני
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ, àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
אשר ימרוך למזמה נשוא לשוא עריך
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ? Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
הלוא-משנאיך יהוה אשנא ובתקוממיך אתקוטט
22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán; èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
תכלית שנאה שנאתים לאויבים היו לי
23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí; dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi.
חקרני אל ודע לבבי בחנני ודע שרעפי
24 Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú kan bá wà nínú mi kí ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.
וראה אם-דרך-עצב בי ונחני בדרך עולם

< Psalms 139 >