< Psalms 135 >
1 Ẹ yin Olúwa. Ẹ yin orúkọ Olúwa; ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa.
Praise Yahweh. Praise the name of Yahweh. Praise him, you servants of Yahweh,
2 Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé Olúwa, nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.
you who stand in Yahweh's house, in the courtyards of the house of our God.
3 Ẹ yin Olúwa: nítorí tí Olúwa ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn.
Praise Yahweh, for he is good; sing praises to his name, for it is pleasant to do so.
4 Nítorí tí Olúwa ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀; àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀.
For Yahweh has chosen Jacob for himself, Israel as his possession.
5 Nítorí tí èmi mọ̀ pé Olúwa tóbi, àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ.
I know that Yahweh is great, that our Lord is above all gods.
6 Olúwa ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
Whatever Yahweh desires, he does in heaven, on earth, in the seas and all the ocean depths.
7 Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá: ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò: ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá.
He brings the clouds from far away, making lightning bolts accompany the rain and bringing the wind out of his storehouse.
8 Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti, àti ti ènìyàn àti ti ẹranko.
He killed the firstborn of Egypt, both of man and animals.
9 Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti, sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
He sent signs and wonders into your midst, Egypt, against Pharaoh and all his servants.
10 Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba.
He attacked many nations and killed mighty kings,
11 Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:
Sihon king of the Amorites and Og king of Bashan and all the kingdoms of Canaan.
12 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀.
He gave us their land as an inheritance, an inheritance to Israel his people.
13 Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé; ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.
Your name, Yahweh, endures forever; your renown, Yahweh, endures throughout all generations.
14 Nítorí tí Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
For Yahweh defends his people and has compassion on his servants.
15 Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni.
The nations' idols are silver and gold, the work of men's hands.
16 Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran.
Those idols have mouths, but they do not speak; they have eyes, but they do not see;
17 Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn.
they have ears, but they do not hear, nor is there breath in their mouths.
18 Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.
Those who make them are like them, as is everyone who trusts in them.
19 Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún Olúwa.
Descendants of Israel, bless Yahweh; descendants of Aaron, bless Yahweh.
20 Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún Olúwa; ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, fi ìbùkún fún Olúwa.
Descendants of Levi, bless Yahweh; you who honor Yahweh, bless Yahweh.
21 Olùbùkún ni Olúwa, láti Sioni wá, tí ń gbé Jerusalẹmu. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Blessed be Yahweh in Zion, he who lives in Jerusalem. Praise Yahweh.