< Psalms 133 >

1 Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Kíyèsi, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún àwọn ará láti máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.
שִׁיר הַֽמַּעֲלוֹת לְדָוִד הִנֵּה מַה־טּוֹב וּמַה־נָּעִים שֶׁבֶת אַחִים גַּם־יָֽחַד׃
2 Ó dàbí òróró ìkunra iyebíye ní orí, tí ó sàn dé irùngbọ̀n, àní irùngbọ̀n Aaroni: tí ó sì sàn sí etí aṣọ sórí rẹ̀.
כַּשֶּׁמֶן הַטּוֹב ׀ עַל־הָרֹאשׁ יֹרֵד עַֽל־הַזָּקָן זְקַֽן־אַהֲרֹן שֶׁיֹּרֵד עַל־פִּי מִדּוֹתָֽיו׃
3 Bí ìrì Hermoni tí o sàn sórí òkè Sioni. Nítorí níbẹ̀ ní Olúwa gbé pàṣẹ ìbùkún, àní ìyè láéláé.
כְּטַל־חֶרְמוֹן שֶׁיֹּרֵד עַל־הַרְרֵי צִיּוֹן כִּי שָׁם ׀ צִוָּה יְהוָה אֶת־הַבְּרָכָה חַיִּים עַד־הָעוֹלָֽם׃

< Psalms 133 >