< Psalms 132 >
1 Orin fún ìgòkè. Olúwa, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
A Song of degrees. LORD, remember David, and all his afflictions:
2 Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa, tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.
How he swore to the LORD, and vowed to the mighty God of Jacob;
3 Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.
Surely I will not come into the tabernacle of my house, nor go up into my bed;
4 Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
I will not give sleep to my eyes, or slumber to my eyelids,
5 títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa, ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.
Until I find a place for the LORD, an habitation for the mighty God of Jacob.
6 Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata: àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
Lo, we heard of it at Ephratah: we found it in the fields of the wood.
7 Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀: àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
We will go into his tabernacles: we will worship at his footstool.
8 Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ: ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
Arise, O LORD, into thy rest; thou, and the ark of thy strength.
9 Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ: kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
Let thy priests be clothed with righteousness; and let thy saints shout for joy.
10 Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
For thy servant David’s sake turn not away the face of thy anointed.
11 Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.
The LORD hath sworn in truth to David; he will not turn from it; Of the fruit of thy body will I set upon thy throne.
12 Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́ àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.
If thy children will keep my covenant and my testimony that I shall teach them, their children also shall sit upon thy throne for evermore.
13 Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni: ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.
For the LORD hath chosen Zion; he hath desired it for his habitation.
14 Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé: níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé: nítorí tí mo fẹ́ ẹ.
This is my rest for ever: here will I dwell; for I have desired it.
15 Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀: èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.
I will abundantly bless her provision: I will satisfy her poor with bread.
16 Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀: àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.
I will also clothe her priests with salvation: and her saints shall shout aloud for joy.
17 Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀, èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.
There will I make the horn of David to bud: I have ordained a lamp for my anointed.
18 Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀: ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.
His enemies will I clothe with shame: but upon himself shall his crown flourish.