< Psalms 131 >

1 Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.
שיר המעלות לדוד יהוה לא-גבה לבי-- ולא-רמו עיני ולא-הלכתי בגדלות ובנפלאות ממני
2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi, mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú: ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
אם-לא שויתי ודוממתי-- נפשי כגמל עלי אמו כגמל עלי נפשי
3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.
יחל ישראל אל-יהוה-- מעתה ועד-עולם

< Psalms 131 >