1Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ.
大衛上行之詩。 耶和華啊,我的心不狂傲, 我的眼不高大; 重大和測不透的事, 我也不敢行。
2Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi, mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú: ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú.
我的心平穩安靜, 好像斷過奶的孩子在他母親的懷中; 我的心在我裏面真像斷過奶的孩子。
3Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé.