< Psalms 130 >
1 Orin fún ìgòkè. Láti inú ibú wá ni èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa
“A psalm of the steps, or the goings up.” Out of the depths do I cry to thee, O LORD!
2 Olúwa, gbóhùn mi, jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
O Lord! listen to my voice, Let thine ears be attentive to my supplication!
3 Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tá ni ìbá dúró.
If thou, LORD, shouldst treasure up transgressions, Lord, who could stand?
4 Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.
But with thee is forgiveness, That thou mayst be feared.
5 Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró, àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.
I trust in the LORD; my soul doth trust, And in his promise do I confide.
6 Ọkàn mi dúró de Olúwa, ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ, àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
My soul waiteth for the LORD More than they who watch for the morning; Yea, more than they who watch for the morning!
7 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa: nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.
O Israel! trust in the LORD! For with the LORD is mercy, And with him is plenteous redemption.
8 Òun ó sì dá Israẹli ní ìdè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
He will redeem Israel From all his iniquities.