< Psalms 13 >

1 Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé? Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
For the Chief Musician. A Psalm of David. How long, O LORD, wilt thou forget me for ever? how long wilt thou hide thy face from me?
2 Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà, àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi? Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?
How long shall I take counsel in my soul, having sorrow in my heart all the day? how long shall mine enemy be exalted over me?
3 Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi. Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú.
Consider [and] answer me, O LORD my God: lighten mine eyes, lest I sleep the [sleep of] death;
4 Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,” àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.
Lest mine enemy say, I have prevailed against him; [lest] mine adversaries rejoice when I am moved.
5 Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà; ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
But I have trusted in thy mercy; my heart shall rejoice in thy salvation:
6 Èmi ó máa kọrin sí Olúwa, nítorí ó dára sí mi.
I will sing unto the LORD, because he hath dealt bountifully with me.

< Psalms 13 >