< Psalms 127 >

1 Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni. Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni; bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
若不是上主興工建屋,建築的人是徒然勞苦;若不是上主護守城堡,守城的人白白驚醒護守。
2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá; bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.
您們很早起床盡屬徒然,每夜坐到深更圖謀打算,為了求食經過多少辛酸;唯獨天主賜所愛者安眠。
3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa: ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
的確子女全是上主的賜予,胎兒也全是他的報酬。
4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe.
年青少壯所生的子嗣,有如勇士手中的箭矢。
5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn; ojú kì yóò tì wọ́n, ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.
裝滿自己箭囊的人,真有福氣,城門前爭辯,不受羞恥。

< Psalms 127 >