< Psalms 126 >

1 Orin fún ìgòkè. Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà, àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
ヱホバ、シオンの俘囚をかへしたまひし時 われらは夢みるもののごとくなりき
2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín, àti ahọ́n wa kọ orin; nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé, Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
そのとき笑はわれらの口にみち歌はわれらの舌にみてり ヱホバかれらのために大なることを作たまへりといへる者もろもろの國のなかにありき
3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa; nítorí náà àwa ń yọ̀.
ヱホバわれらのために大なることをなしたまひたれば我儕はたのしめり
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà, bí ìṣàn omi ní gúúsù.
ヱホバよ願くはわれらの俘囚をみなみの川のごとくに歸したまへ
5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka.
涙とともに播くものは歡喜とともに穫らん
6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.
その人は種をたづさへ涙をながしていでゆけど禾束をたづさへ喜びてかへりきたらん

< Psalms 126 >