< Psalms 124 >

1 Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
שיר המעלות לדוד לולי יהוה שהיה לנו-- יאמר-נא ישראל
2 ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,
לולי יהוה שהיה לנו-- בקום עלינו אדם
3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,
אזי חיים בלעונו-- בחרות אפם בנו
4 nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,
אזי המים שטפונו-- נחלה עבר על-נפשנו
5 nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa.
אזי עבר על-נפשנו-- המים הזידונים
6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
ברוך יהוה-- שלא נתננו טרף לשניהם
7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ.
נפשנו-- כצפור נמלטה מפח יוקשים הפח נשבר ואנחנו נמלטנו
8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé.
עזרנו בשם יהוה-- עשה שמים וארץ

< Psalms 124 >