< Psalms 123 >
1 Orin fún ìgòkè. Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run.
Canticum graduum. Ad te levavi oculos meos, qui habitas in caelis.
2 Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa.
Ecce sicut oculi servorum, in manibus dominorum suorum, Sicut oculi ancillae in manibus dominae suae: ita oculi nostri ad Dominum Deum nostrum donec misereatur nostri.
3 Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀.
Miserere nostri Domine, miserere nostri: quia multum repleti sumus despectione:
4 Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn onírera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.
Quia multum repleta est anima nostra: opprobrium abundantibus, et despectio superbis.