< Psalms 122 >
1 Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sílé Olúwa.”
A Song of degrees of David. I was glad when they said to me, Let us go into the house of the LORD.
2 Ẹsẹ̀ wa yóò dúró ní ẹnu ibodè rẹ, ìwọ Jerusalẹmu.
Our feet shall stand within thy gates, O Jerusalem.
3 Jerusalẹmu, ìwọ tí a kọ́ bí ìlú tí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan.
Jerusalem is built as a city that is compact together:
4 Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ, àwọn ẹ̀yà Olúwa, ẹ̀rí fún Israẹli, láti máa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.
Whither the tribes go up, the tribes of the LORD, to the testimony of Israel, to give thanks to the name of the LORD.
5 Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀, àwọn ìtẹ́ ilé Dafidi.
For there are set thrones of judgment, the thrones of the house of David.
6 Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu; àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.
Pray for the peace of Jerusalem: they shall prosper that love thee.
7 Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀, àti ìre nínú ààfin rẹ̀.
Peace be within thy walls, [and] prosperity within thy palaces.
8 Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mi èmi yóò wí nísinsin yìí pé, kí àlàáfíà kí ó wà nínú rẹ̀.
For my brethren and companions' sake, I will now say, Peace [be] within thee.
9 Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa, èmi yóò máa wá ìre rẹ̀.
Because of the house of the LORD our God I will seek thy good.