< Psalms 121 >

1 Orin fún ìgòkè. Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì— níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?
われ山にむかひて目をあぐ わが扶助はいづこよりきたるや
2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá, ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
わがたすけは天地をつくりたまへるヱホバよりきたる
3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
ヱホバはなんぢの足のうごかさるるを容したまはず 汝をまもるものは微睡たまふことなし
4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.
視よイスラエルを守りたまふものは微睡こともなく寝ることもなからん
5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ; Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
ヱホバは汝をまもる者なり ヱホバはなんぢの右手をおほふ蔭なり
6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.
ひるは日なんぢをうたず夜は月なんぢを傷じ
7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn rẹ mọ́
ヱホバはなんぢを守りてもろもろの禍害をまぬかれしめ並なんぢの霊魂をまもりたまはん
8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.
ヱホバは今よりとこしへにいたるまで 汝のいづると入るとをまもりたまはん

< Psalms 121 >