< Psalms 119 >

1 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa.
行为完全、遵行耶和华律法的, 这人便为有福!
2 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
遵守他的法度、一心寻求他的, 这人便为有福!
3 Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
这人不做非义的事, 但遵行他的道。
4 Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
耶和华啊,你曾将你的训词吩咐我们, 为要我们殷勤遵守。
5 Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
但愿我行事坚定, 得以遵守你的律例。
6 Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
我看重你的一切命令, 就不至于羞愧。
7 Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
我学了你公义的判语, 就要以正直的心称谢你。
8 Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.
我必守你的律例; 求你总不要丢弃我!
9 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
少年人用什么洁净他的行为呢? 是要遵行你的话!
10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
我一心寻求了你; 求你不要叫我偏离你的命令。
11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.
我将你的话藏在心里, 免得我得罪你。
12 Ìyìn ni fún Olúwa; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
耶和华啊,你是应当称颂的! 求你将你的律例教训我!
13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
我用嘴唇传扬你口中的一切典章。
14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ, bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
我喜悦你的法度, 如同喜悦一切的财物。
15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ.
我要默想你的训词, 看重你的道路。
16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ; èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.
我要在你的律例中自乐; 我不忘记你的话。
17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè; èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
求你用厚恩待你的仆人,使我存活, 我就遵守你的话。
18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
求你开我的眼睛, 使我看出你律法中的奇妙。
19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé, má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
我是在地上作寄居的; 求你不要向我隐瞒你的命令!
20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
我时常切慕你的典章, 甚至心碎。
21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
受咒诅、偏离你命令的骄傲人, 你已经责备他们。
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
求你除掉我所受的羞辱和藐视, 因我遵守你的法度。
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
虽有首领坐着妄论我, 你仆人却思想你的律例。
24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi; àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
你的法度是我所喜乐的, 是我的谋士。
25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀; ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
我的性命几乎归于尘土; 求你照你的话将我救活!
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
我述说我所行的,你应允了我; 求你将你的律例教训我!
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ: nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
求你使我明白你的训词, 我就思想你的奇事。
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́; fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
我的心因愁苦而消化; 求你照你的话使我坚立!
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
求你使我离开奸诈的道, 开恩将你的律法赐给我!
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
我拣选了忠信的道, 将你的典章摆在我面前。
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
我持守你的法度; 耶和华啊,求你不要叫我羞愧!
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ, nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
你开广我心的时候, 我就往你命令的道上直奔。
33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
耶和华啊,求你将你的律例指教我, 我必遵守到底!
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
求你赐我悟性,我便遵守你的律法, 且要一心遵守。
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
求你叫我遵行你的命令, 因为这是我所喜乐的。
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
求你使我的心趋向你的法度, 不趋向非义之财。
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
求你叫我转眼不看虚假, 又叫我在你的道中生活。
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára.
你向敬畏你的人所应许的话, 求你向仆人坚定!
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
求你使我所怕的羞辱远离我, 因你的典章本为美。
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
我羡慕你的训词; 求你使我在你的公义上生活!
41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa, ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
耶和华啊,愿你照你的话,使你的慈爱, 就是你的救恩,临到我身上,
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
我就有话回答那羞辱我的, 因我倚靠你的话。
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ.
求你叫真理的话总不离开我口, 因我仰望你的典章。
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé.
我要常守你的律法, 直到永永远远。
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
我要自由而行, 因我素来考究你的训词。
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí,
我也要在君王面前论说你的法度, 并不至于羞愧。
47 nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
我要在你的命令中自乐; 这命令素来是我所爱的。
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
我又要遵行你的命令, 这命令素来是我所爱的; 我也要思想你的律例。
49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
求你记念向你仆人所应许的话, 叫我有盼望。
50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
这话将我救活了; 我在患难中,因此得安慰。
51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
骄傲的人甚侮慢我, 我却未曾偏离你的律法。
52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
耶和华啊,我记念你从古以来的典章, 就得了安慰。
53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
我见恶人离弃你的律法, 就怒气发作,犹如火烧。
54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé.
我在世寄居, 素来以你的律例为诗歌。
55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
耶和华啊,我夜间记念你的名, 遵守你的律法。
56 nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.
我所以如此, 是因我守你的训词。
57 Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.
耶和华是我的福分; 我曾说,我要遵守你的言语。
58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
我一心求过你的恩; 愿你照你的话怜悯我!
59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ.
我思想我所行的道, 就转步归向你的法度。
60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
我急忙遵守你的命令, 并不迟延。
61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
恶人的绳索缠绕我, 我却没有忘记你的律法。
62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo rẹ.
我因你公义的典章, 半夜必起来称谢你。
63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ.
凡敬畏你、守你训词的人, 我都与他作伴。
64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, Olúwa, kọ́ mi ní òfin rẹ.
耶和华啊,你的慈爱遍满大地; 求你将你的律例教训我!
65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa.
耶和华啊,你向来是照你的话善待仆人。
66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ.
求你将精明和知识赐给我, 因我信了你的命令。
67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
我未受苦以先走迷了路, 现在却遵守你的话。
68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
你本为善,所行的也善; 求你将你的律例教训我!
69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
骄傲人编造谎言攻击我, 我却要一心守你的训词。
70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ.
他们心蒙脂油, 我却喜爱你的律法。
71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
我受苦是与我有益, 为要使我学习你的律例。
72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
你口中的训言与我有益, 胜于千万的金银。
73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí; fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ.
你的手制造我,建立我; 求你赐我悟性,可以学习你的命令!
74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi, nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
敬畏你的人见我就要欢喜, 因我仰望你的话。
75 Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.
耶和华啊,我知道你的判语是公义的; 你使我受苦是以诚实待我。
76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.
求你照着应许仆人的话, 以慈爱安慰我。
77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
愿你的慈悲临到我,使我存活, 因你的律法是我所喜爱的。
78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraga nítorí wọn pa mí lára láìnídìí ṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
愿骄傲人蒙羞,因为他们无理地倾覆我; 但我要思想你的训词。
79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi, àwọn tí ó ní òye òfin rẹ.
愿敬畏你的人归向我, 他们就知道你的法度。
80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí.
愿我的心在你的律例上完全, 使我不致蒙羞。
81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
我心渴想你的救恩, 仰望你的应许。
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
我因盼望你的应许眼睛失明,说: 你何时安慰我?
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
我好像烟薰的皮袋, 却不忘记你的律例。
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
你仆人的年日有多少呢? 你几时向逼迫我的人施行审判呢?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin rẹ.
不从你律法的骄傲人为我掘了坑。
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé; ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
你的命令尽都诚实; 他们无理地逼迫我,求你帮助我!
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
他们几乎把我从世上灭绝, 但我没有离弃你的训词。
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
求你照你的慈爱将我救活, 我就遵守你口中的法度。
89 Ọ̀rọ̀ rẹ, Olúwa, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run.
耶和华啊,你的话安定在天, 直到永远。
90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin.
你的诚实存到万代; 你坚定了地,地就长存。
91 Òfin rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́.
天地照你的安排存到今日; 万物都是你的仆役。
92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi.
我若不是喜爱你的律法, 早就在苦难中灭绝了!
93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́.
我永不忘记你的训词, 因你用这训词将我救活了。
94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ.
我是属你的,求你救我, 因我寻求了你的训词。
95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ.
恶人等待我,要灭绝我, 我却要揣摩你的法度。
96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.
我看万事尽都有限, 惟有你的命令极其宽广。
97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
我何等爱慕你的律法, 终日不住地思想。
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ, nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
你的命令常存在我心里, 使我比仇敌有智慧。
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ, nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
我比我的师傅更通达, 因我思想你的法度。
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ, nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
我比年老的更明白, 因我守了你的训词。
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
我禁止我脚走一切的邪路, 为要遵守你的话。
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi.
我没有偏离你的典章, 因为你教训了我。
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
你的言语在我上膛何等甘美, 在我口中比蜜更甜!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
我借着你的训词得以明白, 所以我恨一切的假道。
105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi.
你的话是我脚前的灯, 是我路上的光。
106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọn wí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ.
你公义的典章,我曾起誓遵守, 我必按誓而行。
107 A pọ́n mi lójú gidigidi; Olúwa, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
我甚是受苦; 耶和华啊,求你照你的话将我救活!
108 Olúwa, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi, kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀.
耶和华啊,求你悦纳我口中的赞美为供物, 又将你的典章教训我!
109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ.
我的性命常在危险之中, 我却不忘记你的律法。
110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
恶人为我设下网罗, 我却没有偏离你的训词。
111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé; àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi.
我以你的法度为永远的产业, 因这是我心中所喜爱的。
112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin.
我的心专向你的律例, 永远遵行,一直到底。
113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì, ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ.
心怀二意的人为我所恨; 但你的律法为我所爱。
114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
你是我藏身之处,又是我的盾牌; 我甚仰望你的话语。
115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
作恶的人哪,你们离开我吧! 我好遵守我 神的命令。
116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, kí èmi kí ó lè yè Má sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
求你照你的话扶持我,使我存活, 也不叫我因失望而害羞。
117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu; nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ.
求你扶持我,我便得救, 时常看重你的律例。
118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
凡偏离你律例的人,你都轻弃他们, 因为他们的诡诈必归虚空。
119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́; nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀.
凡地上的恶人,你除掉他,好像除掉渣滓; 因此我爱你的法度。
120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀: èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ.
我因惧怕你,肉就发抖; 我也怕你的判语。
121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́: má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
我行过公平和公义, 求你不要撇下我给欺压我的人!
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú: má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
求你为仆人作保,使我得好处, 不容骄傲人欺压我!
123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ, fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
我因盼望你的救恩 和你公义的话眼睛失明。
124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
求你照你的慈爱待仆人, 将你的律例教训我。
125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye kí èmi lè ní òye òfin rẹ
我是你的仆人,求你赐我悟性, 使我得知你的法度。
126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa; nítorí òfin rẹ ti fọ́.
这是耶和华降罚的时候, 因人废了你的律法。
127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
所以,我爱你的命令胜于金子, 更胜于精金。
128 nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀, èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.
你一切的训词,在万事上我都以为正直; 我却恨恶一切假道。
129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni: nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
你的法度奇妙, 所以我一心谨守。
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá; ó fi òye fún àwọn òpè.
你的言语一解开就发出亮光, 使愚人通达。
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ, nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
我张口而气喘, 因我切慕你的命令。
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi, bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
求你转向我,怜悯我, 好像你素常待那些爱你名的人。
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
求你用你的话使我脚步稳当, 不许什么罪孽辖制我。
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn, kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
求你救我脱离人的欺压, 我要遵守你的训词。
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
求你用脸光照仆人, 又将你的律例教训我。
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi, nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
我的眼泪下流成河, 因为他们不守你的律法。
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin.
耶和华啊,你是公义的; 你的判语也是正直的!
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo: wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
你所命定的法度是凭公义和至诚。
139 Ìtara mi ti pa mí run, nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
我心焦急,如同火烧, 因我敌人忘记你的言语。
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
你的话极其精炼, 所以你的仆人喜爱。
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
我微小,被人藐视, 却不忘记你的训词。
142 Òdodo rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
你的公义永远长存; 你的律法尽都真实。
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi.
我遭遇患难愁苦, 你的命令却是我所喜爱的。
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé; fún mi ní òye kí èmi lè yè.
你的法度永远是公义的; 求你赐我悟性,我就活了。
145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dá mi lóhùn Olúwa, èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
耶和华啊,我一心呼吁你; 求你应允我,我必谨守你的律例!
146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
我向你呼吁,求你救我! 我要遵守你的法度。
147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
我趁天未亮呼求; 我仰望了你的言语。
148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
我趁夜更未换将眼睁开, 为要思想你的话语。
149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ: pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
求你照你的慈爱听我的声音; 耶和华啊,求你照你的典章将我救活!
150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
追求奸恶的人临近了; 他们远离你的律法。
151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa, àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
耶和华啊,你与我相近; 你一切的命令尽都真实!
152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
我因学你的法度, 久已知道是你永远立定的。
153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
求你看顾我的苦难,搭救我, 因我不忘记你的律法。
154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
求你为我辨屈,救赎我, 照你的话将我救活。
155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
救恩远离恶人, 因为他们不寻求你的律例。
156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
耶和华啊,你的慈悲本为大; 求你照你的典章将我救活。
157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
逼迫我的,抵挡我的,很多, 我却没有偏离你的法度。
158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
我看见奸恶的人就甚憎恶, 因为他们不遵守你的话。
159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
你看我怎样爱你的训词! 耶和华啊,求你照你的慈爱将我救活!
160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
你话的总纲是真实; 你一切公义的典章是永远长存。
161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
首领无故地逼迫我, 但我的心畏惧你的言语。
162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
我喜爱你的话, 好像人得了许多掳物。
163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ.
谎话是我所恨恶所憎嫌的; 惟你的律法是我所爱的。
164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ.
我因你公义的典章一天七次赞美你。
165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ, kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀.
爱你律法的人有大平安, 什么都不能使他们绊脚。
166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, Olúwa, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ.
耶和华啊,我仰望了你的救恩, 遵行了你的命令。
167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀.
我心里守了你的法度; 这法度我甚喜爱。
168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi.
我遵守了你的训词和法度, 因我一切所行的都在你面前。
169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, Olúwa; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
耶和华啊,愿我的呼吁达到你面前, 照你的话赐我悟性。
170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
愿我的恳求达到你面前, 照你的话搭救我。
171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
愿我的嘴发出赞美的话, 因为你将律例教训我。
172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.
愿我的舌头歌唱你的话, 因你一切的命令尽都公义。
173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ.
愿你用手帮助我, 因我拣选了你的训词。
174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, Olúwa, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
耶和华啊,我切慕你的救恩! 你的律法也是我所喜爱的。
175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró.
愿我的性命存活,得以赞美你! 愿你的典章帮助我!
176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù. Wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.
我如亡羊走迷了路,求你寻找仆人, 因我不忘记你的命令。

< Psalms 119 >