< Psalms 118 >

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ dúró láéláé.
הודו ליהוה כי-טוב כי לעולם חסדו
2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
יאמר-נא ישראל כי לעולם חסדו
3 Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.
יאמרו-נא בית-אהרן כי לעולם חסדו
4 Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”
יאמרו-נא יראי יהוה כי לעולם חסדו
5 Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa, ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.
מן-המצר קראתי יה ענני במרחב יה
6 Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
יהוה לי לא אירא מה-יעשה לי אדם
7 Olúwa ń bẹ fún mi; òun ni olùrànlọ́wọ́ mi. Nítorí náà ni èmi ó ṣe rí ìṣẹ́gun mi lórí àwọn tí ó kórìíra mi.
יהוה לי בעזרי ואני אראה בשנאי
8 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ.
טוב לחסות ביהוה-- מבטח באדם
9 Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
טוב לחסות ביהוה-- מבטח בנדיבים
10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi káàkiri, ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn kúrò.
כל-גוים סבבוני בשם יהוה כי אמילם
11 Wọ́n yí mi káàkiri ní gbogbo ẹ̀gbẹ́, ṣùgbọ́n ní orúkọ Olúwa èmi gé wọn dànù.
סבוני גם-סבבוני בשם יהוה כי אמילם
12 Wọ́n gbá yìn ìn yí mi ká bí oyin, ṣùgbọ́n wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún; ní orúkọ Olúwa èmi ké wọn dànù.
סבוני כדבורים-- דעכו כאש קוצים בשם יהוה כי אמילם
13 Ìwọ tì mí gidigidi kí n lè ṣubú, ṣùgbọ́n Olúwa ràn mí lọ́wọ́.
דחה דחיתני לנפל ויהוה עזרני
14 Olúwa ni agbára àti orin mi; ó sì di ìgbàlà mi.
עזי וזמרת יה ויהי-לי לישועה
15 Ohùn ayọ̀ àti ìgbàlà ń bẹ nínú àgọ́ àwọn olódodo: “Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!
קול רנה וישועה--באהלי צדיקים ימין יהוה עשה חיל
16 Ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ní a gbéga; ọwọ́ ọ̀tún Olúwa ń ṣe ohun agbára!”
ימין יהוה רוממה ימין יהוה עשה חיל
17 Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè, èmi yóò pòkìkí ohun tí Olúwa ṣe.
לא-אמות כי-אחיה ואספר מעשי יה
18 Olúwa bá mi wí gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
יסר יסרני יה ולמות לא נתנני
19 Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi: èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún Olúwa.
פתחו-לי שערי-צדק אבא-בם אודה יה
20 Èyí ni ìlẹ̀kùn Olúwa ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé.
זה-השער ליהוה צדיקים יבאו בו
21 Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn; ìwọ sì di ìgbàlà mi.
אודך כי עניתני ותהי-לי לישועה
22 Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé;
אבן מאסו הבונים-- היתה לראש פנה
23 Olúwa ti ṣe èyí, ó ṣe ìyanu ní ojú wa.
מאת יהוה היתה זאת היא נפלאת בעינינו
24 Èyí ni ọjọ́ tí Olúwa dá: ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀.
זה-היום עשה יהוה נגילה ונשמחה בו
25 Olúwa, gbà wá; Olúwa, fún wa ní àlàáfíà.
אנא יהוה הושיעה נא אנא יהוה הצליחה נא
26 Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa. Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé Olúwa wá.
ברוך הבא בשם יהוה ברכנוכם מבית יהוה
27 Olúwa ni Ọlọ́run, ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀ ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ.
אל יהוה--ויאר-לנו אסרו-חג בעבתים--עד קרנות המזבח
28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ; ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga.
אלי אתה ואודך אלהי ארוממך
29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
הודו ליהוה כי-טוב כי לעולם חסדו

< Psalms 118 >